Leviticus 9:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sì sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ọmọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ sísun, kí àwọn mejeeji jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì gbọdọ̀ ní àbààwọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ mú obukọ kan wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ati ọmọ malu kan, ati ọdọ-agutan kan, mejeji ọlọdún kan, alailabùku, fun ẹbọ sisun;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí o sì sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọmọ màlúù àti ọ̀dọ́ àgùntàn kan, kí méjèèjì jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun,