Leviticus 9:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Mose sọ fún Aaroni pé, “Súnmọ́ ibi pẹpẹ, kí o sì rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ati ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ ati fún àwọn eniyan náà. Gbé ẹbọ àwọn eniyan náà wá, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si sọ fun Aaroni pe, Sunmọ pẹpẹ, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ, ati ẹbọ sisun rẹ, ki o si ṣètutu fun ara rẹ, ati fun awọn enia: ki o si ru ọrẹ-ẹbọ awọn enia, ki o si ṣètutu fun wọn; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sọ fún Árónì pé, “Wá sí ibi pẹpẹ kí o sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ àti fún àwọn ènìyàn; rú ẹbọ ti àwọn ènìyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ”