Luke 1:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, o óo ya odi, o kò ní lè sọ̀rọ̀ títí ọjọ́ tí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí yóo ṣẹ nígbà tí ó bá yá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, iwọ o yadi, iwọ kì yio si le fọhun, titi ọjọ na ti nkan wọnyi yio fi ṣẹ, nitori iwọ ko gbà ọ̀rọ mi gbọ́ ti yio ṣẹ li akokò wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì kíyèsí i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.”