Luke 1:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò Hẹrọdu, ọba Judia, alufaa kan wà tí ń jẹ́ Sakaraya, ní ìdílé Abiya. Orúkọ iyawo rẹ̀ ni Elisabẹti, láti inú ìdílé Aaroni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigba ọjọ Herodu ọba Judea, alufa kan wà, ni ipa ti Abia, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Sakariah: aya rẹ̀ si ṣe ọkan ninu awọn ọmọbinrin Aaroni, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ Elisabeti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà ọjọ́ Hérọ́dù ọba Jùdéà, Àlùfáà kan wà, ní ipa ti Ábíà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sakaráyà: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìrin Árónì, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Èlísábẹ́tì.