Luke 10:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn èyí, Oluwa yan àwọn mejilelaadọrin mìíràn, ó rán wọn ní meji-meji ṣiwaju rẹ̀ lọ sí gbogbo ìlú ati ibi tí òun náà fẹ́ dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LẸHIN nkan wọnyi, Oluwa si yàn adọrin ọmọ-ẹhin miran pẹlu, o si rán wọn ni mejimeji lọ ṣaju rẹ̀, si gbogbo ilu ati ibi ti on tikararẹ̀ yio gbé de.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn míràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjìméjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkárarẹ̀ yóò sì dé.