Luke 10:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu bá dá a lóhùn pé, “Ọkunrin kan ń ti Jerusalẹmu lọ sí Jẹriko, ni ó bá bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà. Wọ́n gba aṣọ lára rẹ̀, wọ́n lù ú, wọ́n bá fi í sílẹ̀ nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ kú tán.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu si dahùn o wipe, ọkunrin kan nti Jerusalemu sọkalẹ lọ si Jeriko, o si bọ si ọwọ́ awọn ọlọṣà, ti nwọn gbà a li aṣọ, nwọn ṣá a lọgbẹ, nwọn si fi i silẹ lọ li aipa li apatan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán.