Luke 10:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu ilé kan náà ni kí ẹ máa gbé. Ohun tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ fun yín ni kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu. Owó iṣẹ́ alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má máa lọ láti ilé dé ilé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ile kanna ni ki ẹnyin ki o si gbé, ki ẹ mã jẹ, ki ẹ si mã mu ohunkohun ti nwọn ba fifun nyin; nitori ọ̀ya alagbaṣe tọ́ si i. Ẹ maṣe ṣi lati ile de ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
E dúró sínú ilé yẹn, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fifún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe ṣí láti ilé dé ilé.