Luke 11:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ẹ̀mí èṣù náà yóo bá lọ mú àwọn ẹ̀mí meje mìíràn wá tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n óo bá wọ ibẹ̀ wọn óo máa gbébẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà á wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn wọle, nwọn si joko nibẹ̀: igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun tìkárarẹ̀ lọ wá: wọn yóò wọlé, wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀: ìgbẹ̀hìn ọkùnrin náà yóò sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.”