Luke 11:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ̀ ń ṣe ìdámẹ́wàá lórí ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, gbúre ati oríṣìíríṣìí ewébẹ̀, nígbà tí ẹ kò ka ìdájọ́ òdodo ati ìfẹ́ Ọlọrun sí. Àwọn ohun tí ẹ kò kà sí wọnyi ni ó yẹ kí ẹ ṣe, láì gbàgbé àwọn nǹkan yòókù náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin a ma san idamẹwa minti, ati rue, ati gbogbo ewebẹ̀, ṣugbọn ẹnyin gbojufò idajọ ati ifẹ Ọlọrun: wọnyi li ẹnyin iba ṣe, ẹ kì ba si ti fi ekeji silẹ laiṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisí, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá mítì àti rue, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsì fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.