Luke 11:46 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin amòfin náà gbé! Nítorí ẹ̀ ń di ẹrù bàràkàtà-bàràkàtà lé eniyan lórí nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò jẹ́ fi ọwọ́ yín kan ẹrù kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Egbé ni fun ẹnyin amofin pẹlu! nitoriti ẹnyin di ẹrù ti o wuwo lati rù le enia lori, bẹ̃ni ẹnyin tikara nyin kò jẹ fi ika nyin kan kàn ẹrù na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Ègbé ni fún ẹ̀yin amòfin pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin di ẹrù tí ó wúwo láti rù lé ènìyàn lórí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin tìkarayín kò jẹ́ fi ìka yín kan ẹrù náà.