Luke 11:48 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣíṣe tí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fi yín hàn bí ẹlẹ́rìí pé ẹ lóhùn sí ìwà àwọn baba yín: wọ́n pa àwọn wolii, ẹ̀yin wá ṣe ibojì sí ojú-oórì wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ẹnyin njẹ ẹlẹri, ẹ si ni inudidun si iṣe awọn baba nyin: nitori nwọn pa wọn, ẹnyin si kọ́le oju-õrì wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn.