Luke 11:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mò ń sọ fun yín pé, bí kò tilẹ̀ fẹ́ dìde kí ó fún ọ nítorí o jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nítorí tí o kò tijú láti wá kan ìlẹ̀kùn mọ́ ọn lórí lóru, yóo dìde, yóo fún ọ ní ohun tí o nílò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo wi fun nyin, bi on kò tilẹ fẹ dide ki o fifun u, nitoriti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nitori awiyannu rẹ̀ yio dide, yio si fun u pọ̀ to bi o ti nfẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo wí fún yín, bí òun kò tilẹ̀ ti fẹ́ dìde kí ó fifún un nítorí tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí àwíìyánu rẹ̀, yóò dìde, yóò sì fún un pọ̀ tó bí ó ti ń fẹ́.