Luke 12:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ sinu ilé ìpàdé ati siwaju àwọn ìjòyè ati àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe dààmú nípa bí ẹ óo ti ṣe wí àwíjàre tabi pé kí ni ẹ óo sọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn ba si mu nyin wá si sinagogu, ati siwaju awọn olori, ati awọn alaṣẹ, ẹ máṣe ṣàniyàn pe, bawo tabi ohùn kili ẹnyin ó da, tabi kili ẹnyin o wi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí wọ́n bá sì mú yín wá sí sínágọ́gù, àti síwájú àwọn olórí, àti àwọn alásẹ, ẹ má ṣe ṣàníyàn pé, báwo tàbí ohun kínni ẹ̀yin yóò fèsì rẹ̀ tàbí kínni ẹ̀yin ó wí: