Luke 12:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ ṣọ́ra, ẹ ta kété sí ojúkòkòrò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà, nítorí ọ̀pọ̀ dúkìá nìkan kọ́ níí sọni di eniyan.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Kiyesara ki ẹ si mã ṣọra nitori ojukòkoro: nitori igbesi aiye enia ki iduro nipa ọ̀pọ ohun ti o ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsára kí o sì má a sọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”