Luke 12:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Ọlọrun wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè yìí! Ní alẹ́ yìí ni a óo gba ẹ̀mí rẹ pada lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóo wá jogún gbogbo ohun tí o kó jọ wọnyi?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, “Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó bèèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti tani nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?”