Luke 12:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Oluwa sọ pé, “Ta ni olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹni tí oluwa rẹ̀ fi ṣe olórí àwọn iranṣẹ ilé rẹ̀ pé kí ó máa fún wọn ní oúnjẹ lásìkò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si dahùn wipe, Tani olõtọ ati ọlọ́gbọn iriju na, ti oluwa rẹ̀ fi jẹ olori agbo ile rẹ̀, lati ma fi ìwọn onjẹ wọn fun wọn li akokò?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Olúwa sì dáhùn wí pé, “Ta ni olóòótọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú náà, tí olúwa rẹ̀ fi jẹ olórí agbo ilé rẹ̀, láti máa fi ìwọ̀n oúnjẹ wọ̀n fún wọn ní àkókò?