Luke 12:46 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ní ọjọ́ tí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà kò retí, ati ní àkókò tí kò rò tẹ́lẹ̀ ni oluwa rẹ̀ yóo dé, yóo kun ún wẹ́lẹwẹ̀lẹ, yóo sì fún un ní ìpín pẹlu àwọn alaiṣootọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti rẹ̀, ati ni wakati ti kò daba, yio si jẹ ẹ niya gidigidi, yio si yàn ipò rẹ̀ pẹlu awọn alaigbagbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ níyà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.