Luke 12:54 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu tún sọ fún àwọn eniyan pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i tí òjò ṣú ní ìwọ̀ oòrùn, ẹ óo sọ pé, ‘Òjò yóo rọ̀.’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun ijọ enia pẹlu pe, Nigbati ẹnyin ba ri awọsanma ti o ṣú ni ìha ìwọ-õrùn, ọgan ẹnyin a ni, Ọwara òjo mbọ̀; a si ri bẹ̃.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pẹ̀lú pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìkùukù àwọ̀sánmà tí ó ṣú ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, lọ́gán ni ẹ̀yin yóò sọ pé, ‘Ọ̀wàrà òjò ń bọ̀,’ a sì rí bẹ́ẹ̀.