Luke 12:58 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí o bá ń bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ lọ sí kóòtù, gbìyànjú láti yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹlu rẹ̀ bí ẹ ti ń lọ lọ́nà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́. Onídàájọ́ yóo bá fi ọ́ lé ọlọ́pàá lọ́wọ́, ni ọlọ́pàá yóo bá tì ọ́ mọ́lé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba mbá ọtá rẹ lọ sọdọ olóri, mura li ọ̀na ki a le gbà ọ lọwọ rẹ̀; ki o máṣe fi ọ le onidajọ lọwọ, ki onidajọ máṣe fi ọ le ẹṣọ lọwọ, on a si tì ọ sinu tubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ìwọ bá bá ọ̀ta rẹ lọ sọ́dọ̀ onídàájọ́, rí i pé o bá a parí ọ̀rọ̀ ní ọ̀nà kí ó má baà fà ọ́ fún adájọ́, adájọ́ a fi ọ́ lé ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, òun a sì tì ọ́ sínú túbú.