Luke 13:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ báyìí, ojú ti gbogbo àwọn tí ó takò o. Ńṣe ni inú gbogbo àwọn eniyan dùn nítorí gbogbo ohun ìyanu tí ó ń ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si wi nkan wọnyi, oju tì gbogbo awọn ọtá rẹ̀: gbogbo ijọ enia si yọ̀ fun ohun ogo gbogbo ti o ṣe lati ọwọ́ rẹ̀ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀: gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ògo gbogbo tí ó ṣe láti ọwọ́ rẹ̀ wá.