Luke 13:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ rò pé àwọn ará Galili wọnyi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo ará Galili yòókù lọ ni, tí wọ́n fi jẹ irú ìyà yìí?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣebi awọn ara Galili wọnyi ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn ara Galili lọ, nitoriti nwọn jẹ irú ìya bawọnni?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Gálílì wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Gálílì lọ, nítorí wọ́n jẹ iru ìyà báwọ̀n-ọ́n-nì?