Luke 13:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ dù láti gba ẹnu ọ̀nà tí ó há wọlé, nítorí mò ń sọ fun yín pé ọpọlọpọ ni ó ń wá ọ̀nà láti wọlé ṣugbọn wọn kò lè wọlé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ làkaka lati wọ̀ oju-ọ̀na tõro: nitori mo wi fun nyin, enia pipọ ni yio wá ọ̀na ati wọ̀ ọ, nwọn kì yio si le wọle.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé: nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé.