Luke 13:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà nígbà tí ẹ bá rí Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu ati gbogbo àwọn wolii ní ìjọba Ọlọrun, tí wọ́n wá tì yín mọ́ òde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹkún ati ipahinkeke yio wà nibẹ̀, nigbati ẹnyin o ri Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, ati gbogbo awọn woli, ni ijọba Ọlọrun, ti a o si tì ẹnyin sode.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Ábúráhámù, àti Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.