Luke 13:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ fún ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ yẹn pé, ‘Mò ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, mo tún ń ṣe ìwòsàn lónìí ati lọ́la. Ní ọ̀tunla n óo parí iṣẹ́ mi.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ki ẹnyin si sọ fun kọ̀lọkọlọ nì pe, Kiyesi i, emi nlé awọn ẹmi èṣu jade, emi nṣe dida ara loni ati lọla, ati ni ijọ kẹta emi o ṣe aṣepe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsí i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lóní àti lọ́la, àti ní ijọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’