Luke 13:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ òkúta lu àwọn tí a ti rán sí ọ, nígbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tií kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbà fún mi!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn woli, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa; nigba melo li emi nfẹ iradọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ́ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Jerúsálémù, Jerúsálémù, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!