Luke 14:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó wá bi wọ́n pé, “Ta ni ninu yín tí ọmọ rẹ̀, tabi mààlúù rẹ̀ yóo já sinu kànga ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á yọ lẹsẹkẹsẹ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si dahùn o wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti kẹtẹkẹtẹ tabi malu rẹ̀ yio bọ sinu ihò, ti kì yio si fà a soke lojukanna li ọjọ isimi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?”