Luke 15:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò pẹ́ lẹ́yìn rẹ̀ tí àbúrò yìí fi kó gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó bá lọ sí ìlú òkèèrè, ó sá fi ìwà wọ̀bìà ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ pátá ní ìnákúnàá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá.