Luke 16:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Inú rẹ̀ ìbá dùn láti máa jẹ ẹ̀rúnrún tí ó ń bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili olówó yìí. Pẹlu bẹ́ẹ̀ náà, ajá a máa wá lá egbò ara rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On a si ma fẹ ki a fi ẹrún ti o ti ori tabili ọlọrọ̀ bọ silẹ bọ́ on: awọn ajá si wá, nwọn si fá a li õju lá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun: àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.