Luke 16:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ati pé ọ̀gbun ńlá kan wà láàrin àwa ati ẹ̀yin, tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ó bá fẹ́ kọjá sí ọ̀dọ̀ yín kò ní lè kọjá; bákan náà àwọn tí ó bá fẹ́ ti ọ̀hún kọjá wá sí ọ̀dọ̀ wa kò ní lè kọjá.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu gbogbo eyi, a gbe ọgbun nla kan si agbedemeji awa ati ẹnyin, ki awọn ti nfẹ má ba le rekọja lati ìhin lọ sọdọ nyin, ki ẹnikẹni má si le ti ọ̀hun rekọja tọ̀ wa wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má baa le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’