Luke 18:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún un pé, “Nǹkankan ló kù ọ́ kù. Lọ ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka, ìwọ yóo wá ní ìṣúra ní ọ̀run. Kí o máa wá tọ̀ mí lẹ́yìn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Jesu si gbọ́ eyi, o wi fun u pe, Ohun kan li o kù fun ọ sibẹ: lọ ità ohun gbogbo ti o ni, ki o si pín i fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá, ki o mã tọ̀ mi lẹhin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Jésù sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn talákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra lọ́run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
Recommended Reading