Luke 18:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila lọ sápá kan, ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí Jerusalẹmu tí à ń gòkè lọ yìí, gbogbo ohun tí àwọn wolii kọ nípa Ọmọ-Eniyan ni yóo ṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li o pè awọn mejila sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Sawõ, awa ngòke lọ si Jerusalemu, a o si mu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ lati ọwọ́ awọn woli wá, nitori Ọmọ-enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerúsálémù, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn.