Luke 18:43 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lójú kan náà ó sì tún ríran, ó bá ń tẹ̀lé Jesu, ó ń yin Ọlọrun lógo. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lojukanna o si riran, o si ntọ̀ ọ lẹhin, o nyìn Ọlọrun logo: ati gbogbo enia nigbati nwọn ri i, nwọn fi iyìn fun Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.