Luke 19:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ gan-an ni n óo fi ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ burúkú yìí. O mọ̀ pé níbi tí n kò fi nǹkan sí ni mo máa ń wá a sí, ati pé níbi tí n kò fúnrúgbìn sí ni mo ti máa ń kórè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun u pe, Li ẹnu ara rẹ na li emi o ṣe idajọ rẹ, iwọ ọmọ-ọdọ buburu. Iwọ mọ̀ pe onrorò enia ni mi, pe, emi a ma mu eyi ti emi ko fi lelẹ emi a si ma ká eyi ti emi ko gbìn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn;