Luke 19:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu bá dá a lóhùn pé, “Lónìí yìí ni ìgbàlà wọ inú ilé yìí, nítorí ọmọ Abrahamu ni Sakiu náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu si wi fun u pe, Loni ni igbala wọ̀ ile yi, niwọnbi on pẹlu ti jẹ ọmọ Abrahamu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì wí fún un pé, “Lóní ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Ábúráhámù.