Luke 2:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí àwọn angẹli náà ti pada kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-aguntan ń sọ láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtilẹhẹmu tààrà, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tí Oluwa bùn wá gbọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati awọn angẹli na pada kuro lọdọ wọn lọ si ọrun, awọn ọkunrin oluṣọ-agutan na ba ara wọn sọ pe, Ẹ jẹ ki a lọ tàra si Betlehemu, ki a le ri ohun ti o ṣẹ, ti Oluwa fihàn fun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn ańgẹ́lì náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn Olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tàrà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀ jẹ, tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀ fún wa.”