Luke 2:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olùṣọ́-aguntan náà pada síbi iṣẹ́ wọn, wọ́n ń fi ògo ati ìyìn fún Ọlọrun fún gbogbo nǹkan tí wọ́n gbọ́, ati àwọn nǹkan tí wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí angẹli náà ti sọ fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn oluṣọ-agutan si pada lọ, nwọn nfi ogo fun Ọlọrun, nwọn si nyìn i, nitori ohun gbogbo ti nwọn ti gbọ́ ati ti nwọn ti ri, bi a ti wi i fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.