Luke 2:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Simeoni wá súre fún wọn. Ó sọ fún Maria ìyá rẹ̀ pé, “A gbé ọmọ yìí dìde fún ìṣubú ati ìdìde ọpọlọpọ ní Israẹli ati bí àmì tí àwọn eniyan yóo kọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Simeoni si sure fun wọn, o si wi fun Maria iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, a gbé ọmọ yi kalẹ fun iṣubu ati idide ọ̀pọ enia ni Israeli; ati fun àmi ti a nsọ̀rọ òdi si;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síméónì sì súre fún wọn, ó sì wí fún Màríà ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsí i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Ísírẹ́lì; àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀ òdì sí;