Luke 2:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wolii obinrin kan wà tí ń jẹ́ Ana, ọmọ Fanuẹli, ẹ̀yà Aṣeri. Arúgbó kùjọ́kùjọ́ ni. Ọdún meje péré ni ó ṣe ní ilé ọkọ, tí ọkọ rẹ̀ fi kú. Láti ìgbà náà ni ó ti di opó, ó sì tó ẹni ọdún mẹrinlelọgọrin ní àkókò yìí. Kì í fi ìgbà kan kúrò ninu Tẹmpili. Ó ń sìn pẹlu ààwẹ̀ ati ẹ̀bẹ̀ tọ̀sán-tòru.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikan si mbẹ, Anna woli, ọmọbinrin Fanueli, li ẹ̀ya Aseri: ọjọ ogbó rẹ̀ pọ̀, o ti ba ọkọ gbé li ọdún meje lati igba wundia rẹ̀ wá;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnìkan sì ń bẹ, Ánà wòlíì, ọmọbìnrin Fánúénì, ní ẹ̀yà Ásérì: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúndíá rẹ̀ wá;