Luke 20:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili, tí ó ń waasu ìyìn rere fún wọn, àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, ni ijọ kan li ọjọ wọnni, bi o ti nkọ́ awọn enia ni tẹmpili ti o si nwasu ihinrere, awọn olori alufa, ati awọn pẹlu awọn agbagbà dide sí i,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ijọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹ́ḿpìlì tí ó sì ń wàásù ìyìn rere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn alàgbà dìde sí i.