Luke 20:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, ó rán ẹrú rẹ̀ kan sí àwọn alágbàro náà. Ṣugbọn àwọn alágbàro yìí lù ú, wọ́n bá dá a pada ní ọwọ́ òfo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn àgbẹ na, ki nwọn ki o le fun u ninu eso ọgba ajara na: ṣugbọn awọn àgbẹ lù u, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùsọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èṣo ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.