Luke 20:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin yìí tún rán ẹrú mìíràn. Àwọn alágbàro yìí tún lù ú, wọ́n fi àbùkù kàn án, wọ́n bá tún dá òun náà pada ní ọwọ́ òfo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tún rán ọmọ-ọdọ miran: nwọn si lù u pẹlu, nwọn si jẹ ẹ nìya, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tún rán ọmọ-ọ̀dọ̀ míràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ níyà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.