Luke 20:46 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ máa wọ agbádá ńlá. Wọ́n tún gbádùn kí eniyan máa kí wọn ní ààrin ọjà. Wọ́n fẹ́ràn láti jókòó níwájú ninu ilé ìpàdé ati láti jókòó ní ipò ọlá níbi àsè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikí-ni li ọjà, ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi àse;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn ní aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú sínágọ́gù, àti ipò ọlá ní ibi àsè;