Luke 20:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó wá pa òwe yìí fún àwọn eniyan. Ó ní, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu ọgbà kan, ó gba àwọn alágbàro sibẹ, ó bá lọ sí ìrìn àjò. Ó pẹ́ níbi tí ó lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li o bẹ̀rẹ si ipa owe yi fun awọn enia pe; ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si fi ṣe agbatọju fun awọn àgbẹ, o si lọ si àjo fun igba pipẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùsọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́.