Luke 21:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má jẹ́ kí ayẹyẹ, tabi ìfiṣòfò, tabi ọtí mímu, ati àníyàn ayé gba ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé lójijì ni ọjọ́ náà yóo dé ba yín bí ìgbà tí tàkúté bá mú ẹran.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin, ki ọkàn nyin ki o máṣe kún fun wọ̀bia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan aiye yi, ti ọjọ na yio si fi de ba nyin lojijì bi ikẹkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn.