Luke 22:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ẹni tí yóo bá jẹ́ ẹni tí ó ṣe pataki jùlọ ninu yín níláti dàbí ọmọ tí ó kéré jùlọ. Ẹni tí yóo jẹ́ aṣaaju níláti máa ṣe bí iranṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹnyin kì yio ri bẹ̃: ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.