Luke 22:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó wá sọ fún wọn pé, “Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un lọ́wọ́; ẹni tí ó bá ní igbá báárà, kí òun náà gbé e lọ́wọ́. Ẹni tí kò bá ní idà, kí ó ta ẹ̀wù rẹ̀ kí ó fi ra idà kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li o wi fun wọn pe, Ṣugbọn nisisiyi, ẹniti o ba li asuwọn, ki o mu u, ati àpo pẹlu: ẹniti kò ba si ni idà, ki o tà aṣọ rẹ̀, ki o si fi rà kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú; ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ìkan.