Luke 22:47 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ ni àwọn eniyan bá dé. Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ni ó ṣiwaju wọn. Ó bá súnmọ́ Jesu, ó fi ẹnu kò ó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, ọ̀pọ enia, ati ẹniti a npè ni Judasi, ọkan ninu awọn mejila, o ṣaju wọn o sunmọ Jesu lati fi ẹnu kò o li ẹnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsí i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Júdásì, ìkan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jésù láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu.