Luke 23:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó sọ fún wọn pé, “Ẹ fa ọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ mi bí ẹni tí ó ń ba ìlú jẹ́. Lójú yín ni mo wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, tí n kò sì rí àìdára kan tí ó ṣe, ninu gbogbo ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn án.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O sọ fun wọn pe, Ẹnyin mu ọkunrin yi tọ̀ mi wá, bi ẹni ti o npa awọn enia li ọkàn dà: si kiyesi i, emi wadi ẹjọ rẹ̀ niwaju nyin, emi kò si ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi, ni gbogbo nkan wọnyi ti ẹnyin fi i sùn si:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sọ fún wọn pé, “Ẹyin mú ọkùnrin yìí tọ̀ mí wá, bí ẹni tí ó ń yí àwọn ènìyàn ní ọkàn padà: sì kíyèsí i, èmí wádìí ẹjọ́ rẹ̀ níwájú yín èmi kò sì rí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ ọkùnrin yìí, ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ẹ̀yin fi ẹ̀sùn rẹ̀ sùn.