Luke 23:50 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin kan wà ninu àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń jẹ́ Josẹfu. Ó jẹ́ eniyan rere ati olódodo. Òun kò bá wọn lóhùn sí ète tí wọ́n pa, ati ohun tí wọ́n ṣe sí Jesu. Ó jẹ́ ará Arimatia, ìlú kan ní Judia. Ó ń retí ìjọba Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Josefu, ìgbimọ, enia rere, ati olõtọ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jóṣẹ́fù, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatíyà. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòótọ́.