Luke 23:53 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ òkú náà kalẹ̀ lórí agbelebu, ó fi aṣọ funfun wé e, ó bá tẹ́ ẹ sinu ibojì tí wọ́n gbẹ́ sinu àpáta, tí wọn kò ì tíì tẹ́ òkú sí rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ àla dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu okuta, nibiti a kò ti itẹ́ ẹnikẹni si ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí.